Mark 8:31-38

Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú ara rẹ̀

31 aÓ sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn, pé, Ọmọ Ènìyàn kò le ṣàìmá jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ láti ọwọ́ àwọn àgbàgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin, a ó sì pa á, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta yóò sì jíǹde. 32Jesu bá wọn sọ̀rọ̀ yìí, láìfi ohunkóhun pamọ́ fún wọn, ṣùgbọ́n Peteru pe Jesu sẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ si bá a wí.

33 bJesu yípadà, ó wo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sì wí fún Peteru pẹ̀lú ìtara pé, “Kúrò lẹ́yìn mi Satani, nítorí ìwọ kò ro ohun tí Ọlọ́run bí kò ṣe ohun tí ènìyàn.”

Ọ̀nà sí àgbélébùú

34 cNígbà náà ni Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó si gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó si máa tọ̀ mi lẹ́yìn. 35 dNítorí ẹni tó bá gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù. Iye àwọn tí ó sọ ẹ̀mí wọn nù nìkan nítorí í tèmi àti nítorí ìhìnrere, òun náà ni yóò gbà á là. 36Nítorí èrè kí ni ó jẹ́ fún ẹni tí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? 37Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi ṣe pàṣípàrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀? 38 eNítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá tijú àti gbà mí tàbí ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panṣágà àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, tí ó kún fún àìgbàgbọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ báyìí, Ọmọ Ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá padà dé nínú ògo Baba rẹ̀, pẹ̀lú àwọn angẹli mímọ́.”

Mark 9:1

1 fÓ sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín àwọn mìíràn wa nínú àwọn tó dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò tọ́ ikú wò, títí yóò fi rí ìjọba Ọlọ́run tí yóò fi dé pẹ̀lú agbára.”

Copyright information for YorBMYO